Ẹka Èdè Yoruba

NIGERIA CERTIFICATE IN EDUCATION MINIMUM STANDARDS (2020 EDITION)

Introduction

Ẹka Yoruba ní Raphat College of Education, Obaagun, jẹ́ adúróṣinṣin sí ìtọ́jú àti ìtẹ̀síwájú èdè, àṣà àti àjogún Yoruba nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ olùkọ́ tó péye. Eto yìí ń fi ọgbọ́n sọ, ka, kọ, àti kọ́ èdè Yoruba dáadáa sínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́. Ó tún ń kọ́ wọn ní ìgbéraga oríṣìíríṣìí ìdánimọ̀ abinibi, tí ó sì ń mura wọn lẹ́yìn láti kópa nínú ìtẹ̀síwájú àṣà àti ẹ̀kọ́ ní ìpele ìbẹ̀rẹ̀.

Philosophy

Ipa ribiribi ni èdè abínibí ń kó nínú ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè. Kò sí abala tí ọwọ́jà èdè abínibí kò fọwọ́ kàn tán nínú ìṣẹ̀mí ọmọ ènìyàn. Tí ènìyàn bá sọ pé ènìyàn ni èdè tàbí èdè ni ènìyàn, èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ àsọjẹ rárá nítorí pé èdè ló ya ọmọ ènìyàn sọ́tọ̀ sí àwọn ẹ̀dá yòókù. Èyí kì í ṣe èdè lásán, èyí ń túmọ̀ sí èdè àwọn ènìyàn kan. Ìtumọ̀ èyí ni pé orísìí ènìyàn ló wà àti pé èdè pẹ̀ka sí oríṣìíríṣìí ọ̀nà. Èdè ló ń ya àwọn ẹ̀yà ènìyàn kan sọ́tọ̀ sí àwọn mìíràn. Èdè ni irinṣẹ́ àṣà kan gbòógì tó ń ṣàfihàn àwọn ènìyàn láwùjọ. Èdè yìí náà la fi ń ṣe ìgbélárugẹ àjọṣepọ̀, ìtọ́jú àṣà àti ìṣe àti wíwà ní ìsọ̀kan àwọn ẹ̀yà kan. Ìdí nìyí tí ìjọba àpapọ̀ ṣe mú kíkọ́ èdè abínibí ní ọ̀kúnkúndùn.

Objectives of the Programme

The objectives of the programme are to:

  • Jẹ̣́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ìmọ̀ lórí àwọ̣n ìmọ̀ọ́ṣe ìpìlẹ̀ nínú ìfetísílẹ̀, ọ̀rọ̀-sísọ, ìwé-kíkà àti ìwé kíkọ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà àkọtọ́ òde-òní
  • Gbún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní kẹ́ṣẹ́ láti ṣàfihàn ìmọ̀ ìmédèlò, nípa lílo èdè Yorùbá nínú iṣẹ́ ònkọ̀wé alátinúdá, iṣẹ́-ọnà ìbánisọ̀rọ̀ àti ètò ìbánisọ̀rọ̀ ìròyìn.
  • Kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ẹ̀yà ìmọ̀ ẹ̀dá-èdè Yorùbá bí àwọn ìró, ọ̀rọ̀ onítumọ̀ àdámọ́ àti ìhun èdè Yorùbá.
  • Jẹ̣́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mọ̀ nípa àwọn lítírésọ̀ alohùn àti àpilẹ̀kọ tí ó wà ní èdè Yorùbá.
  • jẹ̣́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní òye nípa àṣà oníyebíye tí ó jẹ̣́ ti ìran Yorùbá.
  • Jẹ̣́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mọ̀ ètò ìlànà àti ọ̀nà ti a fi lè lo èdè Yorùbá bí èdè ìkọ́ni fún Ètò Èkọ́ Ìpìlẹ̀ 1 – 3.
  • Jẹ̣́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ìmọ̣̀ lórí ètò ìlànà àti ọ̀nà ìkọ́ni ní èdè Yorùbá
  • Jẹ̣́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní òye tí o yẹ lórí ọ̀nà tí a fi fikún ìmọ̀ ẹni nípàṣẹ iṣẹ́ ìwádìí (ìṣèwádìí).

Admission Requirements

  • A Senior Secondary School Certificate Examination (SSCE) or G.C.E. ‘O’ Level with credits in 5 subjects including English Language and mathematics at not more than two sittings. Two of the credits must be relevant to the course the candidate wishes to offer.
  • All candidates wishing to be considered for admission must meet the requirements of an accredited body such as JAMB.
  • Candidate must pass RACOED screening tests and interviews.

NCE 1

Simẹ́sítà Kin-ín-ní

Course Code Course Title Credit Status
YOR 111 À̀kọtọ́ Yorùbá 2 C
YOR 112 Ìlò Èdè Yorùbá 2 C
YOR 113 Fònẹ́tíìkì Yorùbá 1 C
YOR 114 Ìfáàrà sí Lítírésọ̀ Yorùbá 1 C

Simẹ́sítà Kejì

Course Code Course Title Credit Status
YOR 121 Fonọ́lọ́jì Yorùbá 2 C
YOR 122 Ìtumọ̀ Èdè 1 E
YOR 123 Ìtàn Àṣà àti Ìgbé-ayé Yorùbá 1 E
YOR 124 Ìtàn Àròsọ Àpilẹ̀kọ Yorùbá 2 C

NCE 2

Simẹ́sítà Kin-ín-ní

Course Code Course Title Credit Status
YOR 211 Mofọ́lọ́jì Yorùbá 1 C
YOR 212 Gírámà Yorùbá I 1 C
YOR 213 Eré-oníṣe Àpilẹ̀kọ Yorùbá 1 C
YOR 214 Ọgbọ́n Ìkọ́ni ní Yorùbá I 2 C

Simẹ́sítà Kejì

Course Code Course Title Credit Status
YOR 221 Ọgbọ́n Ìṣèwádìí ní Yorùbá 1 E
YOR 222 Ìfikọ́ra Ìṣẹ àti Ìkọ̀wé Alátinúdá Yorùbá 2 C
YOR 223 Ewì Àpilẹ̀kọ àti àwọn Akéwì Yorùbá 1 E
YOR 224 Ọgbọ́n Ìkọ́ni ní Yorùbá II 1 C

NCE 3

Simẹ́sítà Kin-ín-ní

Course Code Course Title Credit Status
YOR 311 (Kọmọ-n-wò-ọ́) 6 C

Simẹ́sítà Kejì

Course Code Course Title Credit Status
YOR1 321 Gírámà Yorùbá II 1 C
YOR1 322 Àgbéyẹ̀wò Iṣẹ́-ọnà Lítírésọ̀ àti Ìmọ̀ Ìṣọwólò-èdè 2 C
YOR1 323 Ìmọ̀ Ẹ̀rọ àti Sáyẹ́ǹsì Yorùbá 1 E
YOR1 324 Iṣẹ́-gbígbòòrò lórí Lítírésọ̀ Alohùn Yorùbá 1 E