ÈTÒ IṢẸ́ YORÙBÁ

NIGERIA CERTIFICATE IN EDUCATION MINIMUM STANDARDS (2020 EDITION)

Ipa ribiribi ni èdè abínibí ń kó nínú ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè. Kò sí abala tí ọwọ́jà èdè abínibí kò fọwọ́ kàn tán nínú ìṣẹ̀mí ọmọ ènìyàn. Tí ènìyàn bá sọ pé ènìyàn ni èdè tàbí èdè ni ènìyàn, èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ àsọjẹ rárá nítorí pé èdè ló ya ọmọ ènìyàn sọ́tọ̀ sí àwọn ẹ̀dá yòókù. Èyí kì í ṣe èdè lásán, èyí ń túmọ̀ sí èdè àwọn ènìyàn kan. Ìtumọ̀ èyí ni pé orísìí ènìyàn ló wà àti pé èdè pẹ̀ka sí oríṣìíríṣìí ọ̀nà. Èdè ló ń ya àwọn ẹ̀yà ènìyàn kan sọ́tọ̀ sí àwọn mìíràn. Èdè ni irinṣẹ́ àṣà kan gbòógì tó ń ṣàfihàn àwọn ènìyàn láwùjọ. Èdè yìí  náà la fi ń ṣe ìgbélárugẹ àjọṣepọ̀, ìtọ́jú àṣà àti ìṣe àti wíwà ní ìsọ̀kan àwọn ẹ̀yà kan. Ìdí nìyí tí ìjọba àpapọ̀ ṣe mú kíkọ́ èdè abínibí ní ọ̀kúnkúndùn.

Ìlapa ètò iṣẹ́ ÉN-SÍIÌ fún èdè Yorùbá ni a gbé kalẹ̀ láti ;

  1. jẹ̣́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ìmọ̀ lórí àwọ̣n ìmọ̀ọ́ṣe ìpìlẹ̀ nínú ìfetísílẹ̀, ọ̀rọ̀-sísọ, ìwé-kíkà àti ìwé kíkọ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà àkọtọ́ òde-òní;
  2. gbún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní kẹ́ṣẹ́ láti ṣàfihàn ìmọ̀ ìmédèlò, nípa lílo èdè Yorùbá nínú iṣẹ́ ònkọ̀wé alátinúdá, iṣẹ́-ọnà ìbánisọ̀rọ̀ àti ètò ìbánisọ̀rọ̀ ìròyìn;
  3. kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ẹ̀yà ìmọ̀ ẹ̀dá-èdè Yorùbá bí àwọn ìró, ọ̀rọ̀ onítumọ̀ àdámọ́ àti ìhun èdè Yorùbá.
  4. jẹ̣́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mọ̀ nípa àwọn lítírésọ̀ alohùn àti àpilẹ̀kọ tí ó wà ní èdè Yorùbá.
  5. jẹ̣́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní òye nípa àṣà oníyebíye tí ó jẹ̣́ ti ìran Yorùbá
  6. jẹ̣́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mọ̀ ètò ìlànà àti ọ̀nà ti a fi lè lo èdè Yorùbá bí èdè ìkọ́ni fún Ètò Èkọ́ Ìpìlẹ̀ 1 – 3.
  7. jẹ̣́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ìmọ̣̀ lórí ètò ìlànà àti ọ̀nà ìkọ́ni ní èdè Yorùbá; àti
  8. láti jẹ̣́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní òye tí o yẹ lórí ọ̀nà tí a fi fikún ìmọ̀ ẹni nípàṣẹ iṣẹ́ ìwádìí (ìṣèwádìí)
  1. Ìwé ẹ̀rí sẹ́kọ́ńdìrì ìpele kejì tí a mọ̀ sí (SSCE) Wàéèkì/Nẹ́kò, Jíísiiì. Ó gbọ́dọ̀ ní iṣẹ́ márùn-ún tí ó páàsì ní ìpele kírẹ́díìtí nínú èyí tí èdè Yorùbá, èdè Gẹ̀ẹ́sì ati Matimátíìkì gbọdọ̀ wà níbẹ̀. Àwọn iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ̣́ èyí tí akẹ́kọ̀ọ́ ní ní ìjókòó kan, tàbí ní ìjókòó méjì.

    Méjì nínú àwọn Kírẹ́díìtí náà ni o gbọdọ̀ ní nǹkan ṣe pẹ̀lú kọ́ọ̀sì tí aṣèdánwò-wọlé fẹ́ yàn láàyò.

ÌLÀNÀ KỌ́Ọ̀̀SÌ YORÙBÁ

KỌ́Ọ̀SÌKÓ́Ò̀DÙ̀KÍN-IN-NÍ SIMẸ́SÍTÀ KÍN-IN-NÍKÍRẸ́DÍÌTÌIPÒ
ỌDÚN KÌN-ÍN-NÍ SIMẸ́SÍTÀ ỌDÚN KÌN-ÍN-NÍ SIMẸ́SÍTÀ KEJÌ
YOR111À̀kọtọ́ Yorùbá2C
YOR112Ìlò Èdè Yorùbá2C
YOR113Fònẹ́tíìkì Yorùba1C
YOR114Ìfáàrà sí Lítírésọ̀ Yorùbá1C
ỌDÚN KÌN-ÍN-NÍ SIMẸ́SÍTÀ KEJÌỌDÚN KÌN-ÍN-NÍ SIMẸ́SÍTÀ KEJÌ
YOR121Fonọ́lọ́jì Yorùbá2C
YOR122Ìtumọ̀ èdè1E
YOR123Ìtàn Àṣà àti ìgbé-ayé Yorùbá1E
YOR124Ìtàn Àròsọ Àpilẹ̀kọ Yorùbá2C
ỌDÚN KEJÌ SIMẸ́SÍTÀ KÌN-ÍN-NÍ
YOR211Mofọ́lọ́jì Yorùbá1C
YOR212Gírámà Yorùbá I1C
YOR213Eré-oníṣe Àpilẹ̀kọ Yorùbá1C
YOR214Ọgbọ́n Ìkọ́ni ní Yorùbá I2C
ỌDÚN KEJÌ SIMẸ́SÍTÀ KEJÌ
YOR221Ọgbọ́n Ìṣèwádìí ní Yorùbá1E
YOR222Ìfikọ́ra Ìṣẹ àti Ìkọ̀wé Alátinúdá Yorùbá2C
YOR223Ewì Àpilẹ̀kọ àti àwọn Akéwì Yorùbá1E
YOR224Ọgbọ́n Ìkọ́ni ní Yorùbá II1C
ỌDÚN KẸTA SIMẸ́SÍTÀ KÌN-ÍN-NÍ
EDU311(KỌMỌ-N-WÒ-Ọ́)6C
ỌDÚN KẸTA SIMẸ́SÍTÀ KEJÌ
YOR1321Gírámà Yorùbá II1C
YOR1322Àgbéyẹ̀wò iṣẹ́-ọnà Lítírésọ̀ àti Ìmọ̀ Ìṣọwólò-èdè2C
YOR1323Ìmọ̀ Ẹ̀rọ àti Sáyẹ́ǹsì Yorùbá1E
YOR1324Iṣẹ́-gbígbòòrò lórí Lítírésọ̀ Alohùn Yorùbá1E